Proverbs 7

Ìkìlọ̀ nítorí àwọn aṣẹ́wó

1Ọmọ mi, pa ọ̀rọ̀ mi mọ́,
sì fi àwọn òfin mi pamọ́ sínú ọkàn rẹ.
2Pa òfin mi mọ́, ìwọ yóò sì yè
tọ́jú ẹ̀kọ́ mi bí ẹyinlójú rẹ
3Kọ wọ́n sí ọwọ́ òsì rẹ, má ṣe fi jẹun
kọ wọ́n sí inú wàláà àyà rẹ.
4Wí fún ọgbọ́n pé, “Ìwọ ni arábìnrin mi,”
sì pe òye ní ìbátan rẹ;
5Wọn yóò pa ó mọ́ kúrò lọ́wọ́ obìnrin alágbèrè,
kúrò lọ́wọ́ àjèjì obìnrin àti ọ̀rọ̀ ìtànjẹ rẹ̀.

6Ní ojú fèrèsé ilé è mi
mo wo ìta láti ojú fèrèsé.
7Mo rí i láàrín àwọn aláìmọ̀kan
mo sì kíyèsi láàrín àwọn ọ̀dọ́kùnrin,
ọ̀dọ́ kan tí ó ṣe aláìgbọ́n.
8Ó ń lọ ní pópónà ní tòsí i ilé alágbèrè obìnrin náà,
ó ń rìn lọ sí ọ̀nà ilé e rẹ̀
9Ní ìrọ̀lẹ́ bí oòrùn ṣe ń wọ̀,
bí òkùnkùn ṣe ń bo ni lára.

10Bẹ́ẹ̀ ni obìnrin kan jáde wá láti pàdé rẹ̀,
ó múra bí panṣágà pẹ̀lú ètè búburú.
11(Ó jẹ́ aláriwo àti alágídí,
ìdí rẹ̀ kì í jókòó nílé;
12bí ó ti ń já níhìn-ín ní ó ń já lọ́hùn ún
gbogbo orígun ni ó ti ń ba ní ibùba.)
13Ó dìímú, ó sì fẹnukò ó ní ẹnu
pẹ̀lú ojú díndín ó wí pé:

14“Mo ní ọrẹ àlàáfíà ní ilé;
lónìí ni mo san ẹ̀jẹ́ mi.
15Nítorí náà ni n o ṣe jáde wá pàdé è rẹ;
mo wá ọ káàkiri mo sì ti rí ọ!
16Mo ti tẹ́ ibùsùn mi
pẹ̀lú aṣọ aláràbarà láti ilẹ̀ Ejibiti.
17Mo ti fi nǹkan olóòórùn dídùn sí ibùsùn mi
bí i òjìá, aloe àti kinamoni.
18Wá, jẹ́ kí a lo ìfẹ́ papọ̀ ní kíkún títí di àárọ̀;
jẹ́ kí a gbádùn ara wa pẹ̀lú ìfẹ́!
19Ọkọ ọ̀ mi ò sí nílé;
ó ti lọ sí ìrìnàjò jíjìn.
20Ó mú owó púpọ̀ lọ́wọ́
kò sì ní darí dé kí ó tó di ọ̀sán.”

21Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ dídùn ó sì í lọ́nà;
ó tàn án jẹ pẹ̀lú ẹnu dídùn.
22Òun sì tọ̀ ọ́ lọ lẹsẹ̀ kan náà,
bí i màlúù tí ń lọ sí ibùpa,
tàbí bí (aṣiwèrè) àgbọ̀nrín tí ń lọ sí ibi ọgbọ́n ìfabà kọ́.
23Títí tí ọ̀kọ̀ fi gún un ní ẹ̀dọ̀,
bí ẹyẹ ṣe ń fẹ́ wọ inú okùn,
láìmọ̀ pé yóò gba ẹ̀mí òun.

24Nítorí náà báyìí ẹ̀yin ọmọ mi, tẹ́tí sí mi
fọkàn sí nǹkan tí mo sọ.
25Má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ kí ó yà sí ọ̀nà rẹ̀,
tàbí kí ó rìn lọ sí ipa ọ̀nà rẹ̀.
26Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí ó ti fà lulẹ̀
Ogunlọ́gọ̀ àwọn alágbára ni ó ti pa.
27Ilé e rẹ̀ ni ọ̀nà tààrà sí isà òkú,
tí ó lọ tààrà sí àgbàlá ikú.
Copyright information for YorBMYO